Jóòbù
15 Élífásì+ ará Témánì fèsì pé:
2 “Ṣé ọlọ́gbọ́n èèyàn máa fi ọ̀rọ̀ tí kò nítumọ̀* fèsì ni,
Àbí ó máa fi atẹ́gùn ìlà oòrùn kún inú rẹ̀?
3 Fífi ọ̀rọ̀ lásán báni wí kò wúlò,
Ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ò sì ṣàǹfààní.
4 Torí o ti sọ ìbẹ̀rù Ọlọ́run di ahẹrẹpẹ,
O sì mú kí ìrònú nípa Ọlọ́run dín kù.
5 Àṣìṣe rẹ ló ń mú kí o máa sọ̀rọ̀ báyìí,*
O sì yàn láti sọ̀rọ̀ àrékérekè.
6 Ẹnu ara rẹ ló ń dá ọ lẹ́bi, kì í ṣe èmi;
Ètè ìwọ fúnra rẹ sì jẹ́rìí ta kò ọ́.+
7 Ṣé ìwọ ni èèyàn tí wọ́n máa kọ́kọ́ bí,
Àbí wọ́n ti bí ọ ṣáájú àwọn òkè?
8 Ṣé ò ń fetí sí ọ̀rọ̀ àṣírí Ọlọ́run,
Àbí ìwọ nìkan lo rò pé o gbọ́n?
9 Kí lo mọ̀ tí a kò mọ̀?+
Kí ló yé ọ tí kò yé wa?
10 Àwọn tó ní ewú lórí àtàwọn àgbàlagbà wà láàárín wa,+
Àwọn tó dàgbà ju bàbá rẹ lọ fíìfíì.
11 Ṣé ìtùnú Ọlọ́run kò tó ọ ni,
Àbí ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí a bá ọ sọ?
12 Kí ló dé tí ọkàn rẹ ń gbé ọ lọ,
Kí ló sì dé tí ìbínú ń kọ mànà lójú rẹ?
13 Torí o ti mú kí ẹ̀mí rẹ ta ko Ọlọ́run fúnra rẹ̀,
O sì jẹ́ kí irú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ti ẹnu rẹ jáde.
17 Màá sọ fún ọ; fetí sí mi!
Màá ròyìn ohun tí mo rí,
18 Ohun tí àwọn amòye ròyìn, bí wọ́n ṣe gbọ́ ọ lẹ́nu àwọn bàbá wọn,+
Àwọn ohun tí wọn ò fi pa mọ́.
19 Àwọn nìkan la fún ní ilẹ̀ náà,
Àjèjì kankan ò sì gba àárín wọn.
20 Ẹni burúkú ń joró ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀,
Jálẹ̀ gbogbo ọdún tí a yà sọ́tọ̀ fún oníwà ìkà.
21 Etí rẹ̀ ń gbọ́ àwọn ìró tó ń bani lẹ́rù;+
Nígbà àlàáfíà, àwọn tó ń kóni lẹ́rù dìde sí i.
22 Kò gbà gbọ́ pé òun máa bọ́ lọ́wọ́ òkùnkùn;+
A fi í pa mọ́ de idà.
23 Ó ń wá oúnjẹ* kiri, ibo ló wà?
Ó mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ òkùnkùn ti sún mọ́lé.
24 Ìdààmú àti ìrora ń kó jìnnìjìnnì bá a;
Wọ́n borí rẹ̀ bí ọba tó múra tán láti jagun.
25 Torí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí Ọlọ́run fúnra rẹ̀,
Ó sì fẹ́ ta ko* Olódùmarè;
26 Ó fi orí kunkun pa kuuru mọ́ ọn,
Pẹ̀lú apata rẹ̀ tó nípọn tó sì lágbára;*
27 Ọ̀rá mú kí ojú rẹ sanra,
Ọ̀rá sì mú kí ìbàdí rẹ̀ yọ;
28 Ó ń gbé ní àwọn ìlú tó máa pa run,
Nínú àwọn ilé tí ẹnì kankan ò ní gbé,
Tó máa di òkìtì òkúta.
29 Kò ní di ọlọ́rọ̀, ọlá rẹ̀ kò sì ní pọ̀ sí i,
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ohun ìní rẹ̀ kò ní tàn ká ilẹ̀ náà.
30 Kò ní bọ́ lọ́wọ́ òkùnkùn;
Ọwọ́ iná máa mú kí ẹ̀ka igi rẹ̀ gbẹ,*
31 Kó má yà bàrá, kó má sì gbẹ́kẹ̀ lé ohun tí kò ní láárí,
Torí ohun tí kò ní láárí ló máa gbà pa dà;
32 Ó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú ọjọ́ rẹ̀,
Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ò sì ní gbèrú rárá.+
33 Ó máa dà bí èso àjàrà tó gbọn àwọn èso rẹ̀ tí kò tíì pọ́n dà nù
Àti bí igi ólífì tó gbọn ìtànná rẹ̀ dà nù.
35 Wọ́n lóyún ìjàngbọ̀n, wọ́n sì bí ohun tó burú,
Ẹ̀tàn ń ti inú ikùn wọn jáde.”