Àìsáyà
Torí a ti pa á run ní òru kan,
A ti pa Árì+ ti Móábù lẹ́nu mọ́.
Torí a ti pa á run ní òru kan,
A ti pa Kírì+ ti Móábù lẹ́nu mọ́.
Móábù ń sunkún torí Nébò+ àti torí Médébà.+
Wọ́n fá gbogbo orí korodo,+ wọ́n gé gbogbo irùngbọ̀n mọ́lẹ̀.+
3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀* lójú ọ̀nà.
Gbogbo wọn ń pohùn réré ẹkún lórí àwọn òrùlé àtàwọn ojúde ìlú wọn;
Wọ́n ń sunkún bí wọ́n ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ lọ.+
Ìdí nìyẹn tí àwọn ọkùnrin Móábù tó dira ogun fi ń kígbe ṣáá.
Ó* ń gbọ̀n rìrì.
5 Ọkàn mi ń ké jáde torí Móábù.
Àwọn tó sá níbẹ̀ ti sá lọ sí Sóárì+ àti Ẹgilati-ṣẹ́líṣíyà+ lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún.
Wọ́n ń sunkún bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí Lúhítì;
Wọ́n ń ké lójú ọ̀nà Hórónáímù torí àjálù náà.+
6 Torí omi Nímúrímù ti gbẹ táútáú;
Koríko tútù ti gbẹ dà nù,
Kò sí koríko mọ́, kò sì sí ewéko tútù kankan mọ́.
7 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń kó àwọn ohun tó ṣẹ́ kù ní ilé ìkẹ́rùsí wọn àti ọrọ̀ wọn;
Wọ́n ń sọdá àfonífojì àwọn igi pọ́pílà.
8 Torí igbe wọn ń dún ní gbogbo ilẹ̀ Móábù.+
Ìpohùn réré ẹkún náà dé Égíláímù;
Ó lọ títí dé Bia-élímù.
9 Torí ẹ̀jẹ̀ kún inú omi Dímónì,
Mo ṣì máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún Dímónì:
Kìnnìún máa pa àwọn tó yè bọ́ ní Móábù
Àti àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilẹ̀ náà.+