-
Jẹ́nẹ́sísì 37:31-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Wọ́n wá mú aṣọ Jósẹ́fù, wọ́n pa òbúkọ kan, wọ́n sì ti aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 32 Lẹ́yìn náà, wọ́n fi aṣọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ náà ránṣẹ́ sí bàbá wọn, wọ́n sì sọ pé: “Ohun tí a rí nìyí. Jọ̀ọ́, yẹ̀ ẹ́ wò bóyá aṣọ ọmọ rẹ ni tàbí òun kọ́.”+ 33 Ó sì yẹ̀ ẹ́ wò, ló bá kígbe pé: “Aṣọ ọmọ mi ni! Ẹranko burúkú ti pa á jẹ! Ó dájú pé ẹranko náà ti fa Jósẹ́fù ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ!” 34 Ni Jékọ́bù bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sán aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́ ìbàdí, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.
-