Jẹ́nẹ́sísì
44 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún ọkùnrin tó ń bójú tó ilé rẹ̀ pé: “Kó oúnjẹ sínú àpò àwọn ọkùnrin náà, kó sì kún dé ìwọ̀n tí wọ́n á lè gbé, kí o sì fi owó kálukú sí ẹnu àpò+ rẹ̀. 2 Àmọ́ kí o fi ife mi, ife fàdákà, sí ẹnu àpò ẹni tó kéré jù, pẹ̀lú owó ọkà rẹ̀.” Ó sì ṣe ohun tí Jósẹ́fù sọ.
3 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ dáadáa, wọ́n ní kí àwọn ọkùnrin náà máa lọ pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. 4 Wọn ò tíì rìn jìnnà sí ìlú náà nígbà tí Jósẹ́fù sọ fún ọkùnrin tó ń bójú tó ilé rẹ̀ pé: “Dìde! Lé àwọn ọkùnrin yẹn bá! Tí o bá dé ọ̀dọ̀ wọn, sọ fún wọn pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ibi san ire? 5 Ṣebí ohun tí ọ̀gá mi fi ń mu nǹkan nìyí, tó sì máa ń lò dáadáa láti fi woṣẹ́? Ìwà burúkú lẹ hù yìí.’”
6 Ó lé wọn bá, ó sì sọ bẹ́ẹ̀ fún wọn. 7 Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé: “Kí ló dé tí olúwa mi fi ń sọ̀rọ̀ báyìí? Ó dájú pé àwa ìránṣẹ́ rẹ ò lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. 8 Ṣebí a mú owó tí a rí lẹ́nu àpò wa pa dà wá fún ọ láti ilẹ̀ Kénáánì?+ Báwo la ṣe máa wá jí fàdákà tàbí wúrà ní ilé ọ̀gá rẹ? 9 Tí o bá rí i lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwa ẹrú rẹ, ṣe ni kí o pa onítọ̀hún, àwa yòókù náà yóò sì di ẹrú ọ̀gá mi.” 10 Ó wá sọ pé: “Kó rí bí ẹ ṣe sọ: Ẹni tí mo bá rí i nínú ẹrù rẹ̀ yóò di ẹrú mi, àmọ́ kò sóhun tó máa ṣe ẹ̀yin yòókù.” 11 Ni kálukú wọn bá yára sọ àpò rẹ̀ kalẹ̀, wọ́n sì ṣí i. 12 Ó fara balẹ̀ wá a, látorí ẹ̀gbọ́n pátápátá dórí ẹni tó kéré jù. Ó wá rí ife náà nínú àpò+ Bẹ́ńjámínì.
13 Ni wọ́n bá fa aṣọ wọn ya, kálukú wọn gbé ẹrù rẹ̀ pa dà sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, wọ́n sì pa dà sí ìlú náà. 14 Nígbà tí Júdà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ sínú ilé Jósẹ́fù, ó ṣì wà níbẹ̀; wọ́n sì wólẹ̀ síwájú rẹ̀.+ 15 Jósẹ́fù bi wọ́n pé: “Kí lẹ ṣe yìí? Ṣé ẹ ò mọ̀ pé èèyàn bíi tèmi mọ bí wọ́n ṣe ń woṣẹ́+ dáadáa ni?” 16 Ni Júdà bá fèsì pé: “Kí la lè sọ fún ọ̀gá mi? Ọ̀rọ̀ ò dùn lẹ́nu wa. Báwo la ṣe máa fi hàn pé a ò mọwọ́mẹsẹ̀? Ọlọ́run tòótọ́ ti fi àṣìṣe àwa ẹrú+ rẹ hàn. A ti wá di ẹrú ọ̀gá mi, àwa àti ẹni tí wọ́n rí ife náà lọ́wọ́ rẹ̀!” 17 Àmọ́ ó sọ pé: “Mi ò lè ṣe irú ẹ̀ láé! Ẹni tí wọ́n rí ife náà lọ́wọ́ rẹ̀ ni yóò di ẹrú mi.+ Kí ẹ̀yin yòókù máa pa dà lọ sọ́dọ̀ bàbá yín ní àlàáfíà.”
18 Júdà wá sún mọ́ ọn, ó sì sọ pé: “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀gá mi, jọ̀ọ́ jẹ́ kí ẹrú rẹ sọ̀rọ̀ kan létí ọ̀gá mi, má sì bínú sí ẹrú rẹ, torí bíi Fáráò lo jẹ́.+ 19 Ọ̀gá mi bi àwa ẹrú rẹ̀ pé, ‘Ṣé ẹ ní bàbá tàbí àbúrò?’ 20 A sì sọ fún ọ̀gá mi pé, ‘A ní bàbá tó ti darúgbó, ó sì bí ọmọ kan ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, òun ló kéré jù.+ Àmọ́ ẹ̀gbọ́n ọmọ náà ti kú,+ torí náà, òun ló ṣẹ́ kù nínú àwọn ọmọ ìyá+ rẹ̀, bàbá rẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.’ 21 Lẹ́yìn náà, o sọ fún àwa ẹrú rẹ pé, ‘Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi kí n lè rí i.’+ 22 Àmọ́ a sọ fún ọ̀gá mi pé, ‘Ọmọ náà ò lè fi bàbá rẹ̀ sílẹ̀. Tó bá fi í sílẹ̀, ó dájú pé bàbá rẹ̀ máa kú.’+ 23 O sọ fún àwa ẹrú rẹ pé, ‘Ẹ ò ní fojú kàn mí mọ́ àfi tí ẹ bá mú àbúrò yín tó kéré jù dání.’+
24 “A pa dà sọ́dọ̀ ẹrú rẹ tó jẹ́ bàbá mi, a sì sọ ohun tí ọ̀gá mi sọ fún un. 25 Lẹ́yìn náà, bàbá wa sọ pé, ‘Ẹ pa dà lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá fún wa.’+ 26 Àmọ́ a sọ pé, ‘A ò lè lọ. Tí àbúrò wa bá tẹ̀ lé wa, a máa lọ, torí a ò lè fojú kan ọkùnrin náà àfi tí àbúrò wa bá tẹ̀ lé wa lọ.’+ 27 Bàbá mi tó jẹ́ ẹrú rẹ wá sọ fún wa pé, ‘Ẹ mọ̀ dáadáa pé ọmọ méjì péré ni ìyàwó mi bí fún mi.+ 28 Àmọ́ ọ̀kan nínu wọn ti fi mí sílẹ̀, mo sì sọ pé: “Ó dájú pé ẹranko kan ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ!”+ mi ò sì tíì rí i títí di báyìí. 29 Tí ẹ bá tún mú eléyìí kúrò lọ́dọ̀ mi, tí jàǹbá sì lọ ṣe é, ó dájú pé ẹ máa mú ewú orí mi lọ sínú Isà Òkú*+ tòun ti àjálù.’+
30 “Tí mo bá wá pa dà sọ́dọ̀ bàbá mi tó jẹ́ ẹrú rẹ, láìmú ọmọ náà dání, tí ọkàn rẹ̀ sì ti fà mọ́ ọkàn ọmọ yìí, 31 tí kò bá wá rí ọmọ náà, ṣe ló máa kú, àwa ẹrú rẹ yóò sì mú kí bàbá wa tó jẹ́ ẹrú rẹ ṣọ̀fọ̀ wọnú Isà Òkú* pẹ̀lú orí ewú. 32 Ẹrú rẹ fi dá bàbá mi lójú nípa ọmọ náà pé, ‘Tí mi ò bá mú un pa dà wá bá ọ, á jẹ́ pé mo ti ṣẹ bàbá mi títí láé.’+ 33 Torí náà, jọ̀ọ́, jẹ́ kí ẹrú rẹ dúró kí n sì di ẹrú ọ̀gá mi dípò ọmọ náà, kí ọmọ náà lè bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pa dà. 34 Ṣé mo wá lè pa dà sọ́dọ̀ bàbá mi láìmú ọmọ náà dání? Mi ò ní lè wò ó tí àjálù yìí bá dé bá bàbá mi!”