-
Jẹ́nẹ́sísì 28:16-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Jékọ́bù jí lójú oorun, ó sì sọ pé: “Jèhófà wà níbí lóòótọ́, mi ò sì mọ̀.” 17 Ẹ̀rù wá ń bà á, ó sì sọ pé: “Ibí yìí mà ń bani lẹ́rù o! Ó ní láti jẹ́ pé ilé Ọlọ́run+ ni ibí, ẹnubodè ọ̀run+ sì nìyí.” 18 Jékọ́bù wá jí ní àárọ̀ kùtù, ó sì gbé òkúta tó gbórí lé, ó gbé e dúró bí òpó, ó sì da òróró sórí rẹ̀.+ 19 Ó wá pe orúkọ ibẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì,* àmọ́ Lúsì+ ni ìlú náà ń jẹ́ tẹ́lẹ̀.
-