23 Ábúráhámù wá mú Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin tí wọ́n bí nínú ilé rẹ̀ àti gbogbo ẹni tó fi owó rà, gbogbo ọkùnrin inú agbo ilé Ábúráhámù, ó sì dá adọ̀dọ́ wọn* ní ọjọ́ yẹn gan-an, bí Ọlọ́run ṣe sọ fún un.+
3 Torí náà, Ábúráhámù jí ní àárọ̀ kùtù, ó de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀,* ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dání pẹ̀lú Ísákì ọmọ rẹ̀. Ó la igi tó fẹ́ fi dáná ẹbọ sísun náà, ó gbéra, ó sì lọ síbi tí Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un.
12 Ó sì sọ pé: “Má pa ọmọ náà, má sì ṣe ohunkóhun sí i, torí mo ti wá mọ̀ báyìí pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, torí o ò kọ̀ láti fún mi+ ní ọmọ rẹ, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní.”