20 Líà wá sọ pé: “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn, àní ó fún mi ní ẹ̀bùn tó dára. Ní báyìí, ọkọ mi yóò fàyè gbà mí,+ torí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́fà+ fún un.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Sébúlúnì.*+
5 ṣùgbọ́n ó fún Hánà ní ìpín kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, torí pé Hánà ló fẹ́ràn jù, àmọ́ Jèhófà kò tíì fún Hánà ní ọmọ.*6 Yàtọ̀ síyẹn, orogún rẹ̀ ń pẹ̀gàn rẹ̀ ṣáá kó lè múnú bí i nítorí pé Jèhófà kò tíì fún un ní ọmọ.
24 Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara pa mọ́ fún oṣù márùn-ún, ó sọ pé: 25 “Ohun tí Jèhófà* ṣe sí mi ní àwọn ọjọ́ yìí nìyí. Ó ti yíjú sí mi kó lè mú ẹ̀gàn mi kúrò láàárín àwọn èèyàn.”+