Jẹ́nẹ́sísì
30 Nígbà tí Réṣẹ́lì rí i pé òun ò bí ọmọ kankan fún Jékọ́bù, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jowú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó sì ń sọ fún Jékọ́bù pé: “Fún mi ní ọmọ, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, màá kú.” 2 Ni inú bá bí Jékọ́bù sí Réṣẹ́lì, ó sì sọ pé: “Ṣé èmi ni Ọlọ́run tí kò fún ẹ lọ́mọ ni?”* 3 Torí náà, Réṣẹ́lì sọ pé: “Bílíhà+ ẹrúbìnrin mi nìyí. Bá a ní àṣepọ̀ kó lè bímọ fún mi,* kí èmi náà lè ní ọmọ nípasẹ̀ rẹ̀.” 4 Ló bá fún Jékọ́bù ní Bílíhà ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya, Jékọ́bù sì bá a ní àṣepọ̀.+ 5 Bílíhà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Jékọ́bù. 6 Réṣẹ́lì wá sọ pé: “Ọlọ́run ti ṣe onídàájọ́ mi, ó sì ti gbọ́ ohùn mi, ó wá fún mi ní ọmọkùnrin kan.” Ìdí nìyẹn tó fi pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì.*+ 7 Bílíhà, ìránṣẹ́ Réṣẹ́lì tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, nígbà tó yá, ó bí ọmọkùnrin kejì fún Jékọ́bù. 8 Réṣẹ́lì wá sọ pé: “Ìjàkadì gidi ni mo bá ẹ̀gbọ́n mi jà. Mo sì ti borí!” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Náfútálì.*+
9 Nígbà tí Líà rí i pé òun ò bímọ mọ́, ó mú Sílípà ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fún Jékọ́bù pé kó fi ṣe aya.+ 10 Sílípà ìránṣẹ́ Líà sì bí ọmọkùnrin kan fún Jékọ́bù. 11 Líà wá sọ pé: “Ire wọlé dé!” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gádì.*+ 12 Lẹ́yìn náà, Sílípà ìránṣẹ́ Líà bí ọmọkùnrin kejì fún Jékọ́bù. 13 Líà sì sọ pé: “Ayọ̀ mi kún! Ó dájú pé àwọn ọmọbìnrin máa pè mí ní aláyọ̀.”+ Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Áṣérì.*+
14 Nígbà ìkórè àlìkámà,* Rúbẹ́nì+ ń rìn nínú oko, ó sì rí máńdírékì. Ó mú un wá fún Líà ìyá rẹ̀. Réṣẹ́lì wá sọ fún Líà pé: “Jọ̀ọ́, fún mi lára àwọn máńdírékì tí ọmọ rẹ mú wá.” 15 Ló bá sọ fún un pé: “Ṣé ohun kékeré lo rò pé o ṣe nígbà tó o gba ọkọ mi?+ Ṣé o tún fẹ́ gba máńdírékì ọmọ mi ni?” Ni Réṣẹ́lì bá sọ pé: “Kò burú. Màá jẹ́ kó sùn tì ọ́ lálẹ́ òní tí o bá fún mi ní máńdírékì ọmọ rẹ.”
16 Nígbà tí Jékọ́bù ń bọ̀ láti oko ní ìrọ̀lẹ́, Líà lọ pàdé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Èmi lo máa bá ní àṣepọ̀, torí mo ti fi àwọn máńdírékì ọmọ mi gbà ọ́ pátápátá.” Ó wá sùn tì í ní alẹ́ ọjọ́ yẹn. 17 Ọlọ́run fetí sí Líà, ó sì dá a lóhùn, ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin karùn-ún fún Jékọ́bù. 18 Líà sì sọ pé: “Ọlọ́run ti pín mi lérè,* torí mo ti fún ọkọ mi ní ìránṣẹ́ mi.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákà.*+ 19 Líà tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jékọ́bù.+ 20 Líà wá sọ pé: “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn, àní ó fún mi ní ẹ̀bùn tó dára. Ní báyìí, ọkọ mi yóò fàyè gbà mí,+ torí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́fà+ fún un.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Sébúlúnì.*+ 21 Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọbìnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dínà.+
22 Níkẹyìn, Ọlọ́run rántí Réṣẹ́lì, Ọlọ́run fetí sí i, ó sì dá a lóhùn torí ó jẹ́ kó lóyún.*+ 23 Ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó wá sọ pé: “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn+ mi kúrò!” 24 Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jósẹ́fù,*+ ó sì sọ pé: “Jèhófà ti fún mi ní ọmọkùnrin míì.”
25 Lẹ́yìn tí Réṣẹ́lì bí Jósẹ́fù, Jékọ́bù sọ fún Lábánì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Jẹ́ kí n máa lọ, kí n lè pa dà síbi tí mo ti wá àti sí ilẹ̀+ mi. 26 Fún mi ní àwọn ìyàwó mi àti àwọn ọmọ mi, àwọn tí mo torí wọn sìn ọ́, kí n lè máa lọ, torí o mọ bí mo ṣe sìn ọ́ tó.”+ 27 Lábánì wá sọ fún un pé: “Tí mo bá ti rí ojúure rẹ, mo ti rí àmì tó fi hàn pé* torí rẹ ni Jèhófà ṣe ń bù kún mi.” 28 Ó tún sọ pé: “Sọ iye tí o fẹ́ gbà fún mi, màá sì fún ọ.”+ 29 Jékọ́bù fèsì pé: “O mọ bí mo ṣe sìn ọ́, o sì mọ bí mo ṣe tọ́jú agbo ẹran rẹ;+ 30 díẹ̀ lo ní kí n tó dé, àmọ́ agbo ẹran rẹ ti wá pọ̀ sí i, ó ti di púpọ̀ rẹpẹtẹ, Jèhófà sì ti bù kún ọ látìgbà tí mo ti dé. Ìgbà wo ni mo wá fẹ́ ṣe ohun tó máa jẹ́ ti agbo ilé mi?”+
31 Ó wá bi í pé: “Kí ni kí n fún ọ?” Jékọ́bù fèsì pé: “Má ṣe fún mi ní nǹkan kan rárá! Àmọ́ tí o bá máa ṣe ohun kan ṣoṣo yìí fún mi, màá pa dà máa bójú tó agbo àgùntàn rẹ, màá sì máa ṣọ́ wọn.+ 32 Màá gba àárín gbogbo agbo ẹran rẹ kọjá lónìí. Kí o ya gbogbo àgùntàn aláwọ̀ tó-tò-tó àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ sọ́tọ̀ àti gbogbo àgùntàn tí àwọ̀ rẹ̀ pọ́n rẹ́súrẹ́sú* láàárín àwọn ọmọ àgbò. Kí o sì ya èyíkéyìí tó bá ní oríṣiríṣi àwọ̀ àti àwọ̀ tó-tò-tó sọ́tọ̀ láàárín àwọn abo ewúrẹ́. Láti ìsinsìnyí lọ, àwọn yẹn ló máa jẹ́ èrè mi.+ 33 Kí òdodo* tí mò ń ṣe jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní ọjọ́ tí o bá wá wo àwọn tó jẹ́ èrè mi; tí o bá rí èyí tí kì í ṣe aláwọ̀ tó-tò-tó tí kò sì ní oríṣiríṣi àwọ̀ láàárín àwọn abo ewúrẹ́ àti èyí tí àwọ̀ rẹ̀ kò pọ́n rẹ́súrẹ́sú láàárín àwọn ọmọ àgbò lọ́dọ̀ mi, á jẹ́ pé mo jí i ni.”
34 Ni Lábánì bá fèsì pé: “Mo fara mọ́ ọn! Jẹ́ kó rí bí o ṣe sọ.”+ 35 Ní ọjọ́ yẹn, ó ya àwọn òbúkọ abilà àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ sọ́tọ̀ àti gbogbo abo ewúrẹ́ aláwọ̀ tó-tò-tó àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀. Ó ya gbogbo èyí tó ní funfun lára àtàwọn tí àwọ̀ wọn pọ́n rẹ́súrẹ́sú sọ́tọ̀ láàárín àwọn ọmọ àgbò, ó sì ní kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa bójú tó wọn. 36 Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi àyè tó fẹ̀ tó ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta sí àárín òun àti Jékọ́bù, Jékọ́bù sì ń bójú tó èyí tó ṣẹ́ kù nínú agbo ẹran Lábánì.
37 Jékọ́bù wá fi igi tórásì, álímọ́ńdì àti igi adánra* tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gé ṣe ọ̀pá, ó bó àwọn ibì kan lára àwọn ọ̀pá náà sí funfun. 38 Ó wá kó àwọn ọ̀pá tó ti bó náà síwájú agbo ẹran, sínú àwọn kòtò omi, sínú àwọn ọpọ́n ìmumi, níbi tí àwọn agbo ẹran ti wá ń mumi, kí wọ́n lè gùn níwájú àwọn ọ̀pá náà tí wọ́n bá wá mumi.
39 Torí náà, àwọn ẹran náà máa ń gùn níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọ́n sì ń bí àwọn ọmọ tó nílà lára, aláwọ̀ tó-tò-tó àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀. 40 Jékọ́bù wá ya àwọn ọmọ àgbò sọ́tọ̀, ó sì mú kí àwọn agbo ẹran náà kọjú sí àwọn tó jẹ́ abilà àti gbogbo àwọn tí àwọ̀ wọn pọ́n rẹ́súrẹ́sú lára àwọn ẹran Lábánì. Lẹ́yìn náà, ó kó àwọn ẹran tirẹ̀ sọ́tọ̀, kò sì kó wọn mọ́ ti Lábánì. 41 Nígbàkigbà tí àwọn ẹran tó sanra bá fẹ́ gùn, Jékọ́bù máa ń kó àwọn ọ̀pá náà sínú kòtò omi níwájú àwọn agbo ẹran náà, kí wọ́n lè gùn níwájú àwọn ọ̀pá náà. 42 Àmọ́ tí àwọn ẹran náà ò bá lókun, kò ní kó àwọn ọ̀pá náà síbẹ̀. Torí náà, àwọn tí kò lókun yẹn ló máa ń di ti Lábánì, àmọ́ àwọn tó sanra á di ti Jékọ́bù.+
43 Ohun ìní rẹ̀ wá ń pọ̀ sí i, ó ní agbo ẹran tó pọ̀ rẹpẹtẹ, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, ó sì tún ní àwọn ràkúnmí àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+