17 Torí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run+ àti Olúwa àwọn olúwa, Ọlọ́run tó tóbi, tó lágbára, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tí kì í ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni,+ tí kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
7 Ẹ̀rù ba àwọn Filísínì gan-an, wọ́n sọ pé: “Ọlọ́run ti dé sí ibùdó!”+ Ni wọ́n bá sọ pé: “A ti dáràn, nítorí irú èyí ò ṣẹlẹ̀ rí! 8 A ti dáràn! Ta ló máa gbà wá lọ́wọ́ Ọlọ́run títóbi yìí? Ọlọ́run yìí ló pa àwọn ará Íjíbítì lóríṣiríṣi ọ̀nà ní aginjù.+