Diutarónómì
10 “Ìgbà yẹn ni Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Kí ìwọ fúnra rẹ gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́,+ kí o sì wá bá mi lórí òkè náà; kí ìwọ fúnra rẹ tún fi pákó ṣe àpótí.* 2 Màá kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lórí àwọn wàláà àkọ́kọ́ tí o fọ́ túútúú sára wàláà tí o bá gbẹ́, kí o sì gbé e sínú àpótí náà.’ 3 Torí náà, mo fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àpótí kan, mo sì gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́, mo gun òkè náà lọ pẹ̀lú wàláà méjèèjì ní ọwọ́ mi.+ 4 Ó wá kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ti kọ tẹ́lẹ̀ sára àwọn wàláà náà,+ ìyẹn Òfin Mẹ́wàá,*+ tí Jèhófà bá yín sọ lórí òkè náà látinú iná,+ ní ọjọ́ tí ẹ pé jọ;*+ Jèhófà sì kó o fún mi. 5 Mo pa dà, mo sì sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè náà,+ mo gbé àwọn wàláà náà sínú àpótí tí mo ṣe, wọ́n sì wà níbẹ̀, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún mi gẹ́lẹ́.
6 “Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbéra ní Béérótì Bene-jáákánì lọ sí Mósírà. Ibẹ̀ ni Áárónì kú sí, ibẹ̀ sì ni wọ́n sin ín sí,+ Élíásárì ọmọ rẹ̀ wá di àlùfáà dípò rẹ̀.+ 7 Wọ́n gbéra láti ibẹ̀ lọ sí Gúdígódà, láti Gúdígódà lọ sí Jótíbátà,+ ilẹ̀ tó ní àwọn odò tó ń ṣàn.*
8 “Ìgbà yẹn ni Jèhófà ya ẹ̀yà Léfì sọ́tọ̀+ kí wọ́n lè máa gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà,+ kí wọ́n sì máa dúró níwájú Jèhófà, kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ fún un, kí wọ́n sì máa fi orúkọ rẹ̀ súre,+ bí wọ́n ṣe ń ṣe títí dòní. 9 Ìdí nìyẹn tí wọn ò fi fún Léfì ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀. Jèhófà ni ogún rẹ̀, bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe sọ fún un.+ 10 Èmi fúnra mi dúró sórí òkè náà bí mo ṣe ṣe nígbà àkọ́kọ́ fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru,+ Jèhófà sì tún gbọ́ mi ní àkókò yẹn.+ Jèhófà ò fẹ́ pa yín run. 11 Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Máa lọ níwájú àwọn èèyàn náà, kí ẹ múra láti gbéra, kí wọ́n lè lọ gba ilẹ̀ tí mo búra fún àwọn baba ńlá wọn pé màá fún wọn.’+
12 “Ní báyìí, ìwọ Ísírẹ́lì, kí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ kí o ṣe?+ Kò ju pé: kí o máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí o máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí o máa fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ 13 kí o sì máa pa àwọn òfin àti àṣẹ Jèhófà tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́ fún àǹfààní ara rẹ.+ 14 Wò ó, Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló ni ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run,* pẹ̀lú ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀.+ 15 Àwọn baba ńlá yín nìkan ni Jèhófà sún mọ́ tó sì fi ìfẹ́ hàn sí, ó sì ti yan ẹ̀yin ọmọ wọn+ nínú gbogbo èèyàn, bí ẹ ṣe jẹ́ lónìí yìí. 16 Ní báyìí, kí ẹ wẹ ọkàn yín mọ́,*+ kí ẹ má sì ṣe agídí* mọ́.+ 17 Torí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run+ àti Olúwa àwọn olúwa, Ọlọ́run tó tóbi, tó lágbára, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tí kì í ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni,+ tí kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. 18 Ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún ọmọ aláìníbaba* àti opó,+ ó sì nífẹ̀ẹ́ àjèjì,+ ó ń fún un ní oúnjẹ àti aṣọ. 19 Kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ àjèjì, torí ẹ di àjèjì ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
20 “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o máa bẹ̀rù, òun ni kí o máa sìn,+ òun ni kí o rọ̀ mọ́, orúkọ rẹ̀ sì ni kí o máa fi búra. 21 Òun ni Ẹni tí wàá máa yìn.+ Òun ni Ọlọ́run rẹ, tó ṣe gbogbo ohun àgbàyanu àtàwọn ohun tó ń dẹ́rù bani yìí fún ọ, tí o sì fi ojú ara rẹ rí i.+ 22 Àwọn baba ńlá rẹ àti ìdílé wọn jẹ́ àádọ́rin (70) èèyàn* nígbà tí wọ́n lọ sí Íjíbítì,+ àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti mú kí o pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.+