-
1 Kíróníkà 14:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé: “Ṣé kí n lọ gbéjà ko àwọn Filísínì? Ṣé wàá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Ni Jèhófà bá sọ fún un pé: “Lọ, ó dájú pé màá fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”+ 11 Torí náà, Dáfídì lọ sí Baali-pérásímù,+ ó sì pa wọ́n níbẹ̀. Dáfídì wá sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ ti tipasẹ̀ ọwọ́ mi ya lu àwọn ọ̀tá mi, bí ìgbà tí omi bá ya lu nǹkan.” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Baali-pérásímù.* 12 Àwọn Filísínì fi àwọn ọlọ́run wọn sílẹ̀ níbẹ̀, a sì dáná sun+ wọ́n bí Dáfídì ṣe pa á láṣẹ.
-