14 Bí Ábúrámù ṣe gbọ́ pé wọ́n ti mú mọ̀lẹ́bí*+ òun lẹ́rú, ó kó àwọn ọkùnrin tó ti kọ́ ní ogun jíjà, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìdínlógún (318) ìránṣẹ́ tí wọ́n bí sínú agbo ilé rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lé wọn títí dé Dánì.+
34 Mósè wá kúrò ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù lọ sí Òkè Nébò,+ sí orí Písígà,+ tó dojú kọ Jẹ́ríkò.+ Jèhófà sì fi gbogbo ilẹ̀ náà hàn án, láti Gílíádì títí dé Dánì+
20Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Dánì+ títí lọ dé Bíá-ṣébà àti ilẹ̀ Gílíádì,+ gbogbo àpéjọ náà sì kóra jọ sójú kan* níwájú Jèhófà ní Mísípà.+