-
1 Àwọn Ọba 17:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Obìnrin náà wá sọ fún Èlíjà pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé èèyàn Ọlọ́run+ ni ọ́ lóòótọ́ àti pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà lẹ́nu rẹ jẹ́ òótọ́.”
-
-
2 Àwọn Ọba 3:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ni Jèhóṣáfátì bá sọ pé: “Ṣé kò sí wòlíì Jèhófà níbí tó lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà ni?”+ Torí náà, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ọba Ísírẹ́lì dáhùn pé: “Èlíṣà+ ọmọ Ṣáfátì, ẹni tó máa ń bu omi sí ọwọ́ Èlíjà*+ wà níbí.” 12 Lẹ́yìn náà, Jèhóṣáfátì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà wà lẹ́nu rẹ̀.” Torí náà, ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì àti ọba Édómù lọ bá a.
-
-
2 Àwọn Ọba 8:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Nígbà náà, ọba ń bá Géhásì ìránṣẹ́ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ó ní: “Jọ̀wọ́, ròyìn fún mi nípa gbogbo ohun ńlá tí Èlíṣà ti ṣe.”+
-