-
Jeremáyà 38:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ọba Sedekáyà dáhùn pé: “Ẹ wò ó! Ọwọ́ yín ni ọkùnrin náà wà, torí kò sí nǹkan kan tí ọba lè ṣe láti dá yín dúró.”
6 Torí náà, wọ́n mú Jeremáyà, wọ́n sì jù ú sínú kòtò omi Málíkíjà ọmọ ọba, èyí tó wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ Wọ́n fi okùn sọ Jeremáyà kalẹ̀. Nígbà yẹn, kò sí omi nínú kòtò omi náà, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú ẹrẹ̀ náà.
-