Ìsíkíẹ́lì
21 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, yíjú sí Jerúsálẹ́mù, kí o kéde ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ibi mímọ́, kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì. 3 Sọ fún ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Èmi yóò dojú ìjà kọ ọ́, màá fa idà mi yọ nínú àkọ̀,+ màá sì pa olódodo àti ẹni burúkú run láàárín rẹ. 4 Màá fa idà mi yọ nínú àkọ̀ láti bá gbogbo ẹlẹ́ran ara* jà láti gúúsù dé àríwá, torí pé mo fẹ́ pa olódodo àti ẹni burúkú run láàárín rẹ. 5 Gbogbo èèyàn á wá mọ̀ pé, èmi Jèhófà, ti fa idà mi yọ nínú àkọ̀. Kò sì ní pa dà síbẹ̀ mọ́.”’+
6 “Àti ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, mí kanlẹ̀ bí o* ṣe ń gbọ̀n, àní kí o mí kanlẹ̀ nínú ìbànújẹ́ níwájú wọn.+ 7 Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Kí ló dé tí o fi ń mí kanlẹ̀?’ kí o sọ pé, ‘Torí ìròyìn kan ni.’ Torí ó dájú pé ó máa dé, ìbẹ̀rù á sì mú kí gbogbo ọkàn domi, gbogbo ọwọ́ yóò rọ jọwọrọ, ìrẹ̀wẹ̀sì yóò bá gbogbo ẹ̀mí, omi á sì máa ro tótó ní gbogbo orúnkún.*+ ‘Wò ó! Ó dájú pé ó máa dé, ó máa ṣẹlẹ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
8 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 9 “Ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Sọ pé, ‘Idà!+ Wọ́n ti pọ́n idà, wọ́n sì ti dán an. 10 Wọ́n ti pọ́n ọn kó lè pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ; wọ́n ti dán an kó lè máa kọ mànà.’”’”
“Ṣebí ó yẹ ká yọ̀?”
“‘Ṣé ó* máa gé ọ̀pá àṣẹ ọmọ mi ni,+ bó ti ṣe sí gbogbo igi?
11 “‘A ti fi fúnni pé kí a dán an, kí a lè fi ọwọ́ jù ú fìrìfìrì. A ti pọ́n idà yìí, a sì ti dán an, kí a lè fún ẹni tó ń pààyàn.+
12 “‘Sunkún, kí o sì pohùn réré ẹkún,+ ọmọ èèyàn, torí ó ti dojú ìjà kọ àwọn èèyàn mi; ó dojú ìjà kọ gbogbo ìjòyè Ísírẹ́lì.+ Àwọn àti àwọn èèyàn mi ni idà náà máa pa. Torí náà, kí inú rẹ bà jẹ́, kí o sì lu itan rẹ. 13 Torí wọ́n ti yẹ̀ ẹ́ wò,+ kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ tí idà náà bá gé ọ̀pá àṣẹ náà? Kò* ní sí mọ́,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
14 “Ìwọ, ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o pàtẹ́wọ́, kí o sì sọ pé ‘Idà!’ lẹ́ẹ̀mẹta. Idà tó pa àwọn èèyàn, tó pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ ló yí wọn ká.+ 15 Ìbẹ̀rù yóò mú kí ọkàn wọn domi,+ ọ̀pọ̀ yóò sì ṣubú ní àwọn ẹnubodè ìlú wọn; èmi yóò fi idà pa wọ́n. Àní, ó ń kọ mànà, wọ́n sì ti dán an kó lè pa wọ́n! 16 Gé wọn féú féú lápá ọ̀tún! Bọ́ sí apá òsì! Lọ sí ibikíbi tí ojú rẹ bá lọ! 17 Èmi náà yóò pàtẹ́wọ́, màá sì bínú débi tó máa tẹ́ mi lọ́rùn.+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.”
18 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 19 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, la ọ̀nà méjì tí idà ọba Bábílónì yóò gbà wá. Ilẹ̀ kan náà ni méjèèjì yóò ti wá, kí o sì fi àmì* sí ibi tí ọ̀nà náà ti pínyà lọ sí ìlú méjèèjì. 20 La ọ̀nà kan tí idà náà máa gbà wọ Rábà+ ti àwọn ọmọ Ámónì láti bá a jà, kí ọ̀nà kejì sì wọ Jerúsálẹ́mù+ tí odi yí ká, ní Júdà. 21 Torí ọba Bábílónì dúró ní oríta náà, níbi tí ọ̀nà ti pín sí méjì, kó lè woṣẹ́. Ó mi àwọn ọfà. Ó wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà* rẹ̀; ó fi ẹ̀dọ̀ woṣẹ́. 22 Nígbà tó woṣẹ́, ohun tó rí ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ darí wọn sí Jerúsálẹ́mù, pé kí wọ́n gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri, kí wọ́n pàṣẹ láti pa ọ̀pọ̀, kí wọ́n kéde ogun, kí wọ́n gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri ti àwọn ẹnubodè, kí wọ́n mọ òkìtì yí i ká láti dó tì í, kí wọ́n sì fi iyẹ̀pẹ̀ mọ odi yí i ká.+ 23 Àmọ́, ó máa dà bí ìwoṣẹ́ irọ́ lójú àwọn* tó ti búra fún wọn.+ Ṣùgbọ́n ó rántí ẹ̀bi wọn, yóò sì mú wọn.+
24 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Ẹ ti mú kí a rántí ẹ̀bi yín bí ẹ ṣe ń fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín hàn, tí ẹ sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ yín hàn nínú gbogbo ìṣe yín. Ní báyìí tí a sì ti rántí yín, wọ́n á fi ipá* mú yín lọ.’
25 “Àmọ́ ọjọ́ rẹ ti dé, ìgbà tí o máa jìyà ìkẹyìn ti dé, ìwọ ìjòyè tí wọ́n ti ṣe léṣe, ìjòyè burúkú ti Ísírẹ́lì.+ 26 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Tú láwàní, kí o sì ṣí adé.+ Èyí ò ní rí bíi ti tẹ́lẹ̀.+ Gbé ẹni tó rẹlẹ̀ ga,+ kí o sì rẹ ẹni gíga wálẹ̀.+ 27 Àwókù, àwókù, ṣe ni màá sọ ọ́ di àwókù. Kò ní jẹ́ ti ẹnì kankan títí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin fi máa dé,+ òun sì ni èmi yóò fún.’+
28 “Ìwọ ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nípa àwọn ọmọ Ámónì àti nípa ẹ̀gàn wọn nìyí.’ Sọ pé, ‘Idà! Wọ́n ti fa idà yọ láti fi pa wọ́n; wọ́n ti dán an kó lè jẹ nǹkan run, kó sì lè máa kọ mànà. 29 Láìka ìran èké tí wọ́n rí àti iṣẹ́ irọ́ tí wọ́n wò nípa yín sí, wọ́n á kó yín jọ pelemọ sórí àwọn tí wọ́n pa,* àwọn èèyàn burúkú tí ọjọ́ wọn ti dé, ìgbà tí wọ́n máa jìyà ìkẹyìn. 30 Dá a pa dà sínú àkọ̀. Èmi yóò dá ọ lẹ́jọ́ níbi tí a ti ṣẹ̀dá rẹ, ní ilẹ̀ tí o ti wá. 31 Màá bínú sí ọ gidigidi. Ìbínú mi yóò jó ọ bí iná, màá sì mú kí ọwọ́ àwọn ìkà èèyàn tẹ̀ ọ́, àwọn tó mọ bí wọ́n ṣe ń pani run.+ 32 Wọ́n á fi ọ́ dáná;+ wọ́n á ta ẹ̀jẹ̀ rẹ sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà, wọn ò sì ní rántí rẹ mọ́, torí èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.’”