-
1 Sámúẹ́lì 16:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Torí náà, ó ránṣẹ́ pè é, ó sì mú un wọlé. Ọmọ náà pupa, ẹyinjú rẹ̀ mọ́ lóló, ó sì rẹwà gan-an.+ Ni Jèhófà bá sọ pé: “Dìde, fòróró yàn án, torí òun nìyí!”+ 13 Torí náà, Sámúẹ́lì mú ìwo tí òróró wà nínú rẹ̀,+ ó sì fòróró yàn án lójú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún Dáfídì lágbára láti ọjọ́ náà lọ.+ Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì dìde, ó sì gba Rámà lọ.+
-