8 Ó ń rántí májẹ̀mú rẹ̀ títí láé,+
Ìlérí tó ṣe títí dé ẹgbẹ̀rún ìran,+
9 Májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá+
Àti ìbúra rẹ̀ fún Ísákì,+
10 Èyí tó gbé kalẹ̀ bí ìlànà fún Jékọ́bù
Àti bíi májẹ̀mú tó wà títí láé fún Ísírẹ́lì,
11 Ó ní, “Màá fún ọ ní ilẹ̀ Kénáánì+
Bí ogún tí a pín fún yín.”+