13 Ọba Sólómọ́nì ránṣẹ́ sí Hírámù,+ ó sì wá láti Tírè. 14 Ọmọkùnrin opó kan láti inú ẹ̀yà Náfútálì ni, ará Tírè ni bàbá rẹ̀, alágbẹ̀dẹ bàbà+ sì ni. Hírámù mọṣẹ́ gan-an, ó ní òye,+ ó sì mọ bí wọ́n ṣe ń fi bàbà ṣe onírúurú nǹkan. Torí náà, ó wá sọ́dọ̀ Ọba Sólómọ́nì, ó sì ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.