Àwọn Ọba Kìíní
7 Ọdún mẹ́tàlá (13) ló gba Sólómọ́nì láti kọ́ ilé* rẹ̀,+ títí ó fi parí ilé náà látòkèdélẹ̀.+
2 Ó kọ́ Ilé Igbó Lẹ́bánónì,+ gígùn ilé náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́,* fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́, ó kọ́ ọ sórí ọ̀wọ́ mẹ́rin òpó igi kédárì;+ àwọn ìtì igi kédárì sì wà lórí àwọn òpó náà. 3 Wọ́n fi igi kédárì pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí ilé náà lókè, ó wà lórí àwọn ọ̀pá àjà tí ó wà lórí àwọn òpó náà; iye wọn jẹ́ márùndínláàádọ́ta (45), mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ló sì wà nínú ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan. 4 Ọ̀wọ́ mẹ́ta fèrèsé* tó ní férémù ni ó wà, fèrèsé kọ̀ọ̀kan sì dojú kọ fèrèsé míì ní ipele mẹ́ta. 5 Gbogbo ẹnu ọ̀nà àti àwọn òpó ilẹ̀kùn ló ní férémù onígun mẹ́rin tó dọ́gba,* irú férémù yìí náà ló wà ní iwájú àwọn fèrèsé tó dojú kọra tí wọ́n wà ní ipele mẹ́ta.
6 Ó kọ́ Gbọ̀ngàn* Olópòó tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́, ibi àbáwọlé kan sì wà níwájú rẹ̀ tí ó ní àwọn òpó àti ìbòrí.
7 Ó tún kọ́ Gbọ̀ngàn* Ìtẹ́,+ níbi tí yóò ti máa ṣe ìdájọ́, ìyẹn Gbọ̀ngàn Ìdájọ́,+ wọ́n sì fi igi kédárì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ láti ìsàlẹ̀ dé ibi igi ìrólé lókè.
8 Ó kọ́ ilé* tí á máa gbé ní àgbàlá kejì+ sẹ́yìn Gbọ̀ngàn* náà, iṣẹ́ ọnà wọn sì jọra. Ó tún kọ́ ilé kan tí ó dà bíi Gbọ̀ngàn yìí fún ọmọbìnrin Fáráò, ẹni tí Sólómọ́nì fi ṣe aya.+
9 Gbogbo èyí ni a fi òkúta olówó ńlá ṣe,+ tí a sì gbẹ́ bó ṣe wà nínú ìwọ̀n, tí a fi ayùn òkúta rẹ́ nínú àti lóde, láti ìpìlẹ̀ títí dé ìbòrí ògiri àti lóde títí dé àgbàlá ńlá.+ 10 Wọ́n fi àwọn òkúta títóbi, tó jẹ́ olówó ńlá ṣe ìpìlẹ̀ wọn; àwọn òkúta kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, àwọn òkúta míì sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ. 11 Orí wọn ni àwọn òkúta olówó ńlá wà, èyí tí a gbẹ́ bó ṣe wà nínú ìwọ̀n, bẹ́ẹ̀ sì ni igi kédárì. 12 Ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́ kan ìtì igi kédárì yí àgbàlá ńlá náà ká bíi ti àgbàlá inú+ ilé Jèhófà àti ibi àbáwọlé* ilé náà.+
13 Ọba Sólómọ́nì ránṣẹ́ sí Hírámù,+ ó sì wá láti Tírè. 14 Ọmọkùnrin opó kan láti inú ẹ̀yà Náfútálì ni, ará Tírè ni bàbá rẹ̀, alágbẹ̀dẹ bàbà+ sì ni. Hírámù mọṣẹ́ gan-an, ó ní òye,+ ó sì mọ bí wọ́n ṣe ń fi bàbà* ṣe onírúurú nǹkan. Torí náà, ó wá sọ́dọ̀ Ọba Sólómọ́nì, ó sì ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.
15 Ó mọ òpó bàbà méjì;+ gíga òpó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún (18), okùn ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjìlá (12) lè yí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òpó náà ká.*+ 16 Ó fi bàbà rọ ọpọ́n méjì sórí àwọn òpó náà. Gíga ọpọ́n kìíní jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga ọpọ́n kejì sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. 17 Ó fi ẹ̀wọ̀n ṣe iṣẹ́ ọnà tó dà bí àwọ̀n sórí ọpọ́n tó wà lórí òpó kọ̀ọ̀kan;+ méje sára ọpọ́n kìíní àti méje sára ọpọ́n kejì. 18 Ó ṣe ìlà méjì pómégíránétì yí àwọ̀n náà ká láti bo ọpọ́n tó wà lórí òpó náà; ohun kan náà ni ó ṣe sí ọpọ́n méjèèjì. 19 Àwọn ọpọ́n tó wà lórí àwọn òpó ibi àbáwọlé* náà ní iṣẹ́ ọnà lára, èyí tó dà bí òdòdó lílì, tí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. 20 Àwọn ọpọ́n náà wà lórí òpó méjì náà, àwọ̀n sì wà lára ibi tó rí rogodo lápá ìsàlẹ̀ ọpọ́n náà; igba (200) pómégíránétì sì wà lórí àwọn ìlà tó yí ọpọ́n kọ̀ọ̀kan ká.+
21 Ó ṣe àwọn òpó ibi àbáwọlé* tẹ́ńpìlì.*+ Ó ṣe òpó apá ọ̀tún,* ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jákínì,* lẹ́yìn náà, ó ṣe òpó apá òsì,* ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bóásì.*+ 22 Iṣẹ́ ọnà tó dà bí òdòdó lílì wà lórí àwọn òpó náà. Bí iṣẹ́ àwọn òpó náà ṣe parí nìyẹn.
23 Lẹ́yìn náà, ó fi irin ṣe Òkun.*+ Ó rí ribiti, fífẹ̀ ẹnu rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, okùn ìdíwọ̀n ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́ ló sì lè yí i ká.*+ 24 Àwọn iṣẹ́ ọnà tó rí bí akèrègbè+ wà nísàlẹ̀ ẹnu rẹ̀ yí ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan, wọ́n yí Òkun náà po, ìlà méjì àwọn iṣẹ́ ọnà tó rí bí akèrègbè náà ni ó ṣe mọ́ ọn lára. 25 Wọ́n gbé Òkun náà ka orí akọ màlúù méjìlá (12),+ mẹ́ta dojú kọ àríwá, mẹ́ta dojú kọ ìwọ̀ oòrùn, mẹ́ta dojú kọ gúúsù, mẹ́ta sì dojú kọ ìlà oòrùn; Òkun náà wà lórí wọn, gbogbo wọn sì kọ̀dí sí abẹ́ Òkun náà. 26 Ìnípọn rẹ̀ jẹ́ ìbú ọwọ́ kan;* ẹnu rẹ̀ sì dà bí ẹnu ife, bí ìtànná òdòdó lílì. Ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) báàtì* ni ó ń gbà.
27 Ó fi bàbà ṣe kẹ̀kẹ́ ẹrù*+ mẹ́wàá. Gígùn kẹ̀kẹ́ ẹrù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta. 28 Bí wọ́n ṣe ṣe àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù náà nìyí: Wọ́n ní àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́, àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ náà sì wà láàárín àwọn ọ̀pá ìdábùú. 29 Àwọn kìnnìún,+ akọ màlúù àti kérúbù+ sì wà lára àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ tó wà láàárín àwọn ọ̀pá ìdábùú náà, iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ kan náà ló wà lára àwọn ọ̀pá ìdábùú náà. Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tó so kọ́ra wà lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún àti àwọn akọ màlúù náà. 30 Kẹ̀kẹ́ ẹrù kọ̀ọ̀kan ní àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rin tí a fi bàbà ṣe àti àwọn ọ̀pá àgbá kẹ̀kẹ́ tí a fi bàbà ṣe, ọ̀pá igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jẹ́ agbóhunró. Bàsíà náà wà lórí àwọn agbóhunró tí a ṣe ohun ọ̀ṣọ́ tó so kọ́ra mọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́. 31 Ohun ọ̀ṣọ́ tó dà bí adé wà ní ibi ẹnu bàsíà náà, láti ìdí bàsíà náà sókè jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan; ẹnu kẹ̀kẹ́ ẹrù náà rí ribiti, gíga ẹnu náà lápapọ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀, wọ́n fín iṣẹ́ ọnà sí ibi ẹnu rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní igun mẹ́rin tó dọ́gba, wọn kò rí ribiti. 32 Àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà nísàlẹ̀ àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ náà, wọ́n so ọ̀pá igun àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà mọ́ kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, gíga àgbá kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀. 33 Wọ́n ṣe àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà bí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin. Irin ni wọ́n fi rọ gbogbo ọ̀pá igun wọn, ríìmù wọn, sípóòkù wọn àti họ́ọ̀bù wọn. 34 Agbóhunró mẹ́rin ló wà lára igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kẹ̀kẹ́ ẹrù kọ̀ọ̀kan; wọ́n ṣe àwọn agbóhunró náà mọ́ ara* kẹ̀kẹ́ ẹrù náà. 35 Ohun ọ̀ṣọ́ to ṣe ribiti wà lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, gíga rẹ̀ jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, àwọn férémù kéékèèké àti àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni a ṣe mọ́* ara rẹ̀. 36 Ó fín àwọn kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ sára àwọn férémù kéékèèké àti sára àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ bí àyè tó wà lára ọ̀kọ̀ọ̀kan ṣe fẹ̀ tó, ó sì ṣe ohun ọ̀ṣọ́ tó so kọ́ra yí i ká.+ 37 Bí ó ti ṣe kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá+ náà nìyẹn; bákan náà ni ó rọ gbogbo wọn,+ ìwọ̀n kan náà ni wọ́n, bákan náà ni wọ́n sì rí.
38 Ó ṣe bàsíà bàbà+ mẹ́wàá; ogójì (40) òṣùwọ̀n báàtì ni bàsíà kọ̀ọ̀kan ń gbà. Ìwọ̀n bàsíà kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin.* Kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ní bàsíà kọ̀ọ̀kan lórí. 39 Lẹ́yìn náà, ó gbé kẹ̀kẹ́ ẹrù márùn-ún sí apá ọ̀tún ilé náà àti márùn-ún sí apá òsì ilé náà, ó sì gbé Òkun náà sí apá ọ̀tún ilé náà láàárín gúúsù àti ìlà oòrùn.+
40 Hírámù+ tún ṣe àwọn bàsíà, àwọn ṣọ́bìrì+ àti àwọn abọ́.+ Bẹ́ẹ̀ ni Hírámù parí gbogbo iṣẹ́ ilé Jèhófà+ tó ṣe fún Ọba Sólómọ́nì, ìyẹn: 41 àwọn òpó méjèèjì+ àti àwọn ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí òpó méjèèjì; iṣẹ́ ọnà méjèèjì+ tó dà bí àwọ̀n tó fi bo ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí àwọn òpó náà; 42 ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) pómégíránétì+ fún iṣẹ́ ọnà méjì tó dà bí àwọ̀n, ìlà méjì pómégíránétì fún iṣẹ́ ọnà kọ̀ọ̀kan tó dà bí àwọ̀n, tó fi bo ọpọ́n méjèèjì tó rí bí abọ́ lórí òpó méjèèjì; 43 kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá+ àti bàsíà mẹ́wẹ̀ẹ̀wá+ tó wà lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù náà; 44 Òkun náà+ àti akọ màlúù méjìlá (12) tó wà lábẹ́ Òkun náà; 45 àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn abọ́ àti gbogbo àwọn nǹkan èlò tí Hírámù fi bàbà dídán ṣe fún Ọba Sólómọ́nì fún ilé Jèhófà. 46 Agbègbè Jọ́dánì ni ọba ti rọ wọ́n nínú ohun tó fi amọ̀ ṣe, láàárín Súkótù àti Sárétánì.
47 Sólómọ́nì fi gbogbo nǹkan èlò náà sílẹ̀ láìwọ̀n wọ́n nítorí wọ́n ti pọ̀ jù. A kò mọ bí ìwọ̀n bàbà náà ṣe pọ̀ tó.+ 48 Sólómọ́nì ṣe gbogbo nǹkan èlò ilé Jèhófà, àwọn ni: pẹpẹ+ wúrà; tábìlì wúrà+ tí wọ́n á máa kó búrẹ́dì àfihàn sí; 49 àwọn ọ̀pá fìtílà+ tí a fi ògidì wúrà ṣe, márùn-ún lápá ọ̀tún àti márùn-ún lápá òsì níwájú yàrá inú lọ́hùn-ún; àwọn ìtànná òdòdó,+ àwọn fìtílà àti àwọn ìpaná* tí a fi wúrà ṣe;+ 50 àwọn bàsíà, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà,+ àwọn abọ́, àwọn ife+ àti àwọn ìkóná+ tí á fi ògidì wúrà ṣe; ihò àwọn ilẹ̀kùn ilé inú lọ́hùn-ún,+ ìyẹn, Ibi Mímọ́ Jù Lọ àti ihò àwọn ilẹ̀kùn ilé tẹ́ńpìlì+ tí a fi wúrà ṣe.
51 Torí náà, Ọba Sólómọ́nì parí gbogbo iṣẹ́ ilé Jèhófà tó yẹ ní ṣíṣe. Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì kó àwọn ohun tí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́+ wọlé, ó kó fàdákà, wúrà àti àwọn ohun èlò wá sínú ibi tí wọ́n ń kó ìṣúra sí ní ilé Jèhófà.+