-
Jeremáyà 29:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ẹ ó pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, màá sì fetí sí yín.’+
-
-
Jeremáyà 50:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 “Ní àwọn ọjọ́ yẹn àti ní àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí, “àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti àwọn èèyàn Júdà máa kóra jọ.+ Wọ́n á máa sunkún bí wọ́n ṣe ń rìn lọ,+ wọ́n á sì jọ máa wá Jèhófà Ọlọ́run wọn.+ 5 Wọ́n á béèrè ọ̀nà tó lọ sí Síónì, wọ́n á yíjú sí apá ibẹ̀,+ wọ́n á ní, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a bá Jèhófà dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé, tí kò sì ní ṣeé gbàgbé.’+
-