-
1 Àwọn Ọba 11:1-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Àmọ́ Ọba Sólómọ́nì nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin ilẹ̀ àjèjì,+ yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Fáráò,+ àwọn tó tún nífẹ̀ẹ́ ni: àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ Móábù,+ ọmọ Ámónì,+ ọmọ Édómù, ọmọ Sídónì+ àti ọmọ Hétì.+ 2 Wọ́n wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ lọ sí àárín wọn,* wọn ò sì gbọ́dọ̀ wá sí àárín yín, torí ó dájú pé wọ́n á mú kí ọkàn yín fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run wọn.”+ Àmọ́ ọkàn Sólómọ́nì kò kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. 3 Ó ní ọgọ́rùn-ún méje (700) ìyàwó tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọba àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) wáhàrì,* ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìyàwó rẹ̀ yí i lọ́kàn pa dà.* 4 Nígbà tí Sólómọ́nì darúgbó,+ àwọn ìyàwó rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run míì,+ kò sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bíi Dáfídì bàbá rẹ̀. 5 Sólómọ́nì yíjú sí Áṣítórétì,+ abo ọlọ́run àwọn ọmọ Sídónì àti Mílíkómù,+ ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Ámónì.
-