2 Àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá Mósè jà,+ wọ́n sì ń sọ pé: “Fún wa lómi mu.” Àmọ́ Mósè bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń bá mi jà? Kí ló dé tí ẹ̀ ń dán Jèhófà wò?”+
8 ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bó ṣe rí nígbà tí ẹ fa ìbínú tó le gan-an, bíi ti ọjọ́ tí ẹ fa àdánwò ní aginjù,+9 níbi tí àwọn baba ńlá yín ti dán mi wò, tí wọ́n sì dẹ mí wò, láìka àwọn iṣẹ́ mi tí wọ́n rí fún ogójì (40) ọdún sí.+