-
Sáàmù 30:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Ẹkún lè wà ní àṣálẹ́, àmọ́ tó bá di àárọ̀, igbe ayọ̀ á sọ.+
-
-
Àìsáyà 61:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
61 Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wà lára mi,+
Torí Jèhófà ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+
Ó rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn,
Láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú,
Pé ojú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì máa là rekete,+
2 Láti kéde ọdún ìtẹ́wọ́gbà* Jèhófà
Àti ọjọ́ ẹ̀san Ọlọ́run wa,+
Láti tu gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú,+
3 Láti pèsè fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ torí Síónì,
Láti fún wọn ní ìwérí dípò eérú,
Òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,
Aṣọ ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.
-