-
1 Àwọn Ọba 3:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi, o ti fi ìránṣẹ́ rẹ jọba ní ipò Dáfídì bàbá mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́* ni mí, tí mi ò sì ní ìrírí.*+ 8 Ìránṣẹ́ rẹ wà lára àwọn èèyàn rẹ tí o yàn,+ àwọn èèyàn tó pọ̀ gan-an débi pé wọn ò níye, wọn ò sì ṣeé kà. 9 Torí náà, fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọkàn tó ń gbọ́ràn láti máa fi ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ,+ láti fi mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú,+ torí ta ló lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ tó pọ̀ gan-an* yìí?”
-