22 Níkẹyìn, Ọlọ́run rántí Réṣẹ́lì, Ọlọ́run fetí sí i, ó sì dá a lóhùn torí ó jẹ́ kó lóyún.*+23 Ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó wá sọ pé: “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn+ mi kúrò!”
24 Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara pa mọ́ fún oṣù márùn-ún, ó sọ pé: 25 “Ohun tí Jèhófà* ṣe sí mi ní àwọn ọjọ́ yìí nìyí. Ó ti yíjú sí mi kó lè mú ẹ̀gàn mi kúrò láàárín àwọn èèyàn.”+