19 Mikáyà bá sọ pé: “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: Mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀,+ gbogbo ọmọ ogun ọ̀run sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, lápá ọ̀tún àti lápá òsì.+
9 “Mò ń wò títí a fi gbé àwọn ìtẹ́ kalẹ̀, tí Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé+ sì jókòó.+ Aṣọ rẹ̀ funfun bíi yìnyín,+ irun orí rẹ̀ sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ọwọ́ iná ni ìtẹ́ rẹ̀; iná tó ń jó ni àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀.+