6Ní ọdún tí Ọba Ùsáyà kú,+ mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ gíga, tó sì ta yọ,+ etí aṣọ rẹ̀ kún inú tẹ́ńpìlì. 2 Àwọn séráfù dúró lókè rẹ̀; ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ mẹ́fà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan* fi méjì bo ojú, ó fi méjì bo ẹsẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń fi méjì fò kiri.
2 Lẹ́yìn èyí, mo wà nínú agbára ẹ̀mí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, sì wò ó! ìtẹ́ kan wà ní àyè rẹ̀ ní ọ̀run, ẹnì kan sì jókòó sórí ìtẹ́ náà.+3 Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ náà rí bí òkúta jásípérì+ àti òkúta sádísì,* òṣùmàrè kan tó dà bí òkúta émírádì sì wà yí ká ìtẹ́ náà.+