-
2 Àwọn Ọba 18:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ọba Ásíríà wá rán àwọn mẹ́ta tí orúkọ oyè wọn ń jẹ́ Tátánì* àti Rábúsárísì* àti Rábúṣákè* pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun láti Lákíṣì+ sí Ọba Hẹsikáyà ní Jerúsálẹ́mù.+ Wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dúró síbi tí adágún omi tó wà lápá òkè ń gbà, èyí tó wà lójú ọ̀nà tó lọ sí pápá alágbàfọ̀.+ 18 Nígbà tí wọ́n pe ọba pé kó jáde, Élíákímù+ ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣẹ́bínà+ akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí jáde wá bá wọn.
-