24 “‘Élámù+ àti gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ wà níbẹ̀ tí wọ́n yí sàréè rẹ̀ ká, gbogbo wọn ni wọ́n fi idà pa. Wọ́n ti lọ sí ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀ láìdádọ̀dọ́,* àwọn tí wọ́n dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè. Ojú á wá tì wọ́n pẹ̀lú àwọn tó ń lọ sínú kòtò.*
8 Báwo ló ṣe wá jẹ́ pé kálukú wa ń gbọ́ èdè ìbílẹ̀* rẹ̀? 9 Àwọn tó wà pẹ̀lú wa ni àwọn ará Pátíà, àwọn ará Mídíà+ àti àwọn ọmọ Élámù,+ àwọn tó ń gbé Mesopotámíà, Jùdíà àti Kapadókíà, Pọ́ńtù àti ìpínlẹ̀ Éṣíà,+