5 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ìgbà wo ni àjọ̀dún òṣùpá tuntun máa parí,+ ká lè ta àwọn hóró ọkà wa,
Àti ìparí Sábáàtì,+ ká lè gbé hóró ọkà lọ fún títà?
Ká lè sọ òṣùwọ̀n eéfà di kékeré
Kí a sì sọ ṣékélì di ńlá,
Kí a dọ́gbọ́n sí àwọn òṣùwọ̀n wa, kí a lè fi tanni jẹ;+
6 Kí a lè fi fàdákà ra àwọn aláìní
Kí a sì fi owó bàtà ẹsẹ̀ méjì ra àwọn tálákà,+
Kí a sì lè ta èyí tí kò dáa lára ọkà.’