2 Èmi yóò tún kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ,
Èmi yóò sì mú wọn sọ̀ kalẹ̀ wá sí Àfonífojì Jèhóṣáfátì.
Èmi yóò dá wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀+
Nítorí àwọn èèyàn mi àti torí Ísírẹ́lì ogún mi,
Wọ́n ti tú wọn ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè,
Wọ́n sì ti pín ilẹ̀ mi láàárín ara wọn.+