-
Ìsíkíẹ́lì 35:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Torí o sọ pé, ‘Orílẹ̀-èdè méjì yìí àti ilẹ̀ méjì yìí yóò di tèmi, méjèèjì á sì di ohun ìní wa,’+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ wà níbẹ̀, 11 ‘torí náà, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘bí o ṣe bínú sí wọn, tí o sì jowú wọn torí pé o kórìíra wọn ni èmi náà yóò ṣe sí ọ;+ màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ mí nígbà tí mo bá dá ọ lẹ́jọ́.
-
-
Sefanáyà 2:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “Mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ẹnu Móábù+ àti èébú àwọn ọmọ Ámónì,+
Àwọn tó kẹ́gàn àwọn èèyàn mi, tí wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ wọn láti gba ilẹ̀ wọn.+
9 Nítorí náà, bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí,
“Móábù máa dà bíi Sódómù gẹ́lẹ́,+
Àti àwọn ọmọ Ámónì bíi Gòmórà,+
Ibi tí èsìsì wà, tí kòtò iyọ̀ wà, tó sì ti di ahoro títí láé.+
Àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn mi á kó wọn lọ,
Àwọn tó ṣẹ́ kù nínú orílẹ̀-èdè mi á sì gba tọwọ́ wọn.
-