28 Lẹ́yìn tí ọba gba ìmọ̀ràn, ó ṣe ère ọmọ màlúù wúrà méjì,+ ó sì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Wàhálà yìí ti pọ̀ jù fún yín láti máa lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ọlọ́run rẹ rèé, ìwọ Ísírẹ́lì, tí ó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+ 29 Ìgbà náà ni ó gbé ọ̀kan sí Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì gbé ìkejì sí Dánì.+