ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 61:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Dípò ìtìjú, ẹ máa ní ìpín ìlọ́po méjì,

      Dípò ìdójútì, wọ́n máa kígbe ayọ̀ nítorí ìpín wọn.

      Àní, ìpín ìlọ́po méjì ni wọ́n máa gbà ní ilẹ̀ wọn.+

      Wọ́n á máa yọ̀ títí ayérayé.+

  • Jeremáyà 30:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 “Ní tìrẹ, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, má fòyà,” ni Jèhófà wí,

      “Má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì.+

      Nítorí màá gbà ọ́ láti ibi tó jìnnà réré

      Àti àwọn ọmọ rẹ láti oko ẹrú tí wọ́n wà.+

      Jékọ́bù á pa dà, ara rẹ̀ á balẹ̀, kò ní rí ìyọlẹ́nu,

      Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”+

  • Jeremáyà 33:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Màá mú àwọn ará Júdà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lóko ẹrú pa dà,+ màá sì fún wọn lókun bí mo ti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀.+

  • Jeremáyà 33:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Orúkọ ìlú yìí máa gbé mi ga, á sì mú kí wọ́n máa yìn mí, kí wọ́n sì máa fi ògo fún mi láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé tó máa gbọ́ nípa gbogbo oore tí mo ṣe fún ìlú náà.+ Ẹ̀rù á bà wọ́n, wọ́n á sì máa gbọ̀n+ nítorí gbogbo oore àti àlàáfíà tí màá mú bá ìlú náà.’”+

  • Ìsíkíẹ́lì 39:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò dá àwọn èèyàn Jékọ́bù tí wọ́n kó lẹ́rú pa dà,+ màá sì ṣàánú gbogbo ilé Ísírẹ́lì;+ èmi yóò fi ìtara gbèjà orúkọ mímọ́ mi.*+

  • Ìsíkíẹ́lì 39:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Nígbà tí mo bá mú wọn pa dà láti ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn, tí mo sì kó wọn jọ láti ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn,+ èmi yóò tún mú kí wọ́n mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí lójú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.’+

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́