34 Torí èyí, mò ń rán àwọn wòlíì,+ àwọn amòye àtàwọn tó ń kọ́ni ní gbangba+ sí yín. Ẹ máa pa àwọn kan lára wọn,+ ẹ sì máa kàn wọ́n mọ́gi,* ẹ máa na àwọn kan lára wọn+ nínú àwọn sínágọ́gù yín, ẹ sì máa ṣe inúnibíni sí wọn+ láti ìlú dé ìlú,
8Sọ́ọ̀lù, ní tirẹ̀, fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe pa Sítéfánù.+
Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni tó lágbára sí ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù; gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn tú ká lọ sí gbogbo agbègbè Jùdíà àti Samáríà, àwọn àpọ́sítélì nìkan ni kò tú ká.+