-
Máàkù 7:25-30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ní ẹ̀mí àìmọ́ gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì wá wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 26 Ará Gíríìsì ni obìnrin náà, ọmọ* ilẹ̀ Foníṣíà ní Síríà; ó sì ń bẹ̀ ẹ́ ṣáá pé kó lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ọmọbìnrin òun. 27 Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Jẹ́ kí àwọn ọmọ kọ́kọ́ yó ná, torí kò tọ́ ká mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, ká sì jù ú sí àwọn ajá kéékèèké.”+ 28 Àmọ́ obìnrin náà dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni sà, síbẹ̀, àwọn ajá kéékèèké tó wà lábẹ́ tábìlì pàápàá, máa ń jẹ lára èérún tó já bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ kéékèèké.” 29 Ó wá sọ fún un pé: “Torí ohun tí o sọ yìí, máa lọ; ẹ̀mí èṣù náà ti kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”+ 30 Torí náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó sì rí i tí ọmọ kékeré náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn, ẹ̀mí èṣù náà ti kúrò lára rẹ̀.+
-