-
Mátíù 15:22-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Wò ó! obìnrin ará Foníṣíà kan láti agbègbè yẹn wá, ó sì ń ké jáde pé: “Ṣàánú mi, Olúwa, Ọmọ Dáfídì. Ẹ̀mí èṣù ń yọ ọmọbìnrin mi lẹ́nu gidigidi.”+ 23 Àmọ́ kò dá a lóhùn rárá. Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ ọ́ pé: “Ní kó máa lọ, torí kò yéé ké tẹ̀ lé wa.” 24 Ó fèsì pé: “A kò rán mi sí ẹnikẹ́ni àfi àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.”+ 25 Àmọ́ obìnrin náà wá tẹrí ba* fún un, ó sì ń sọ pé: “Olúwa, ràn mí lọ́wọ́!” 26 Ó fèsì pé: “Kò tọ́ ká mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, ká sì jù ú sí àwọn ajá kéékèèké.” 27 Obìnrin náà sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, àmọ́ ká sòótọ́, àwọn ajá kéékèèké máa ń jẹ lára èérún tó ń já bọ́ látorí tábìlì àwọn ọ̀gá wọn.”+ 28 Jésù wá dá a lóhùn pé: “Ìwọ obìnrin yìí, ìgbàgbọ́ rẹ lágbára gan-an; kó ṣẹlẹ̀ sí ọ bí o ṣe fẹ́.” Ara ọmọbìnrin rẹ̀ sì yá láti wákàtí yẹn lọ.
-