42 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó kúrò lọ sí ibì kan tó dá.+ Àmọ́ àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí í wá a,* wọ́n dé ibi tó wà, wọ́n sì gbìyànjú láti dá a dúró kó má bàa kúrò lọ́dọ̀ wọn.
7 Nígbà tí Kristi wà ní ayé,* ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀, ó sì fi ẹkún tó rinlẹ̀ àti omijé tọrọ+ lọ́wọ́ Ẹni tó lè gbà á lọ́wọ́ ikú, a sì gbọ́ ọ, a ṣojúure sí i torí pé ó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.