-
Máàkù 1:35-38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 Ní àárọ̀ kùtù, tí ilẹ̀ ò tíì mọ́, ó dìde, ó jáde lọ síbi tó dá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà níbẹ̀.+ 36 Àmọ́ Símónì àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá a kàn, 37 wọ́n sì rí i, wọ́n wá sọ fún un pé: “Gbogbo èèyàn ti ń wá ọ.” 38 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká lọ síbòmíì, sí àwọn ìlú tó wà nítòsí, kí n lè wàásù níbẹ̀ náà, torí ìdí tí mo ṣe wá nìyí.”+
-