27Nígbà tó di àárọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà gbìmọ̀ pọ̀ kí wọ́n lè pa Jésù.+2 Lẹ́yìn tí wọ́n dè é, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fà á lé Pílátù lọ́wọ́, òun ni gómìnà.+
66 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kóra jọ,+ wọ́n sì mú un lọ sínú gbọ̀ngàn Sàhẹ́ndìrìn wọn, wọ́n sọ pé:
28 Wọ́n wá mú Jésù látọ̀dọ̀ Káyáfà lọ sí ilé gómìnà.+ Àárọ̀ kùtù ni. Àmọ́ àwọn fúnra wọn ò wọnú ilé gómìnà, kí wọ́n má bàa sọ ara wọn di aláìmọ́,+ kí wọ́n lè jẹ Ìrékọjá.
13 Ọlọ́run Ábúráhámù àti ti Ísákì àti ti Jékọ́bù,+ Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ti ṣe Jésù,+ Ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo,+ ẹni tí ẹ fà lé àwọn èèyàn lọ́wọ́,+ tí ẹ sì sọ níwájú Pílátù pé ẹ ò mọ̀ rí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pinnu pé òun máa dá a sílẹ̀.