-
Lúùkù 4:33-35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 Ọkùnrin kan wà nínú sínágọ́gù náà tó ní ẹ̀mí kan, ẹ̀mí èṣù àìmọ́, ó sì kígbe pé:+ 34 “Áà! Kí ló pa wá pọ̀, Jésù ará Násárẹ́tì?+ Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́ gan-an, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run ni ọ́.”+ 35 Àmọ́ Jésù bá a wí, ó ní: “Dákẹ́, kí o sì jáde kúrò nínú rẹ̀.” Torí náà, lẹ́yìn tí ẹ̀mí èṣù náà gbé ọkùnrin náà ṣánlẹ̀ láàárín wọn, ó jáde kúrò nínú rẹ̀ láìṣe é léṣe.
-