-
Mátíù 12:9-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Lẹ́yìn tó kúrò níbẹ̀, ó lọ sínú sínágọ́gù wọn, 10 wò ó! ọkùnrin kan wà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ!+ Kí wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án, wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bófin mu láti ṣe ìwòsàn ní Sábáàtì?”+ 11 Ó sọ fún wọn pé: “Tí ẹ bá ní àgùntàn kan, tí àgùntàn náà sì já sínú kòtò ní Sábáàtì, ṣé ẹnì kan wà nínú yín tí kò ní dì í mú, kó sì gbé e jáde?+ 12 Ṣé èèyàn ò wá ṣeyebíye ju àgùntàn lọ? Torí náà, ó bófin mu láti ṣe ohun tó dáa ní Sábáàtì.” 13 Ó wá sọ fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa dà rí bíi ti ọwọ́ kejì. 14 Àmọ́ àwọn Farisí jáde lọ, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.
-
-
Máàkù 3:1-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ó tún wọ inú sínágọ́gù kan, ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ rọ sì wà níbẹ̀.+ 2 Wọ́n wá ń ṣọ́ ọ lójú méjèèjì, wọ́n ń wò ó bóyá ó máa wo ọkùnrin náà sàn ní Sábáàtì, kí wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án. 3 Ó sọ fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé: “Dìde, máa bọ̀ ní àárín.” 4 Lẹ́yìn náà, ó bi wọ́n pé: “Ṣé ó bófin mu ní Sábáàtì láti ṣe rere tàbí láti ṣe ibi, láti gba ẹ̀mí* là tàbí láti pa á?”+ Àmọ́ wọn ò sọ̀rọ̀. 5 Lẹ́yìn tó wò wọ́n yí ká tìbínútìbínú, tí ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi torí pé ọkàn wọn ti yigbì,+ ó sọ fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó na ọwọ́ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. 6 Ni àwọn Farisí bá jáde lọ, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù+ gbìmọ̀ pọ̀, kí wọ́n lè pa á.
-