-
Nọ́ńbà 6:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì pé òun fẹ́ di Násírì*+ fún Jèhófà, 3 kó yẹra fún wáìnì àti àwọn ohun mímu míì tó ní ọtí. Kó má mu ohun kíkan tí wọ́n fi wáìnì ṣe tàbí ohun kíkan tí wọ́n fi nǹkan tó ní ọtí+ ṣe. Kó má mu ohunkóhun tí wọ́n fi èso àjàrà ṣe, kó má sì jẹ èso àjàrà, ì báà jẹ́ tútù tàbí gbígbẹ.
-
-
Lúùkù 1:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, Sekaráyà, torí a ti ṣojúure sí ọ, a sì ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin kan fún ọ, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jòhánù.+
-