ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 26:47-50
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 47 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! Júdásì, ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà dé pẹ̀lú èrò rẹpẹtẹ tí wọ́n kó idà àti kùmọ̀ dání, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà ló rán wọn wá.+

      48 Ẹni tó fẹ́ dà á ti fún wọn ní àmì kan, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fẹnu kò lẹ́nu, òun ni ẹni náà; kí ẹ mú un.” 49 Ó wá lọ tààràtà sọ́dọ̀ Jésù, ó sọ pé: “Mo kí ọ o, Rábì!” ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 50 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Ọ̀gbẹ́ni, kí lo wá ṣe níbí?”+ Ni wọ́n bá wá síwájú, wọ́n gbá Jésù mú, wọ́n sì mú un sọ́dọ̀.

  • Máàkù 14:43-46
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 43 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Júdásì, ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà dé pẹ̀lú èrò tí wọ́n kó idà àti kùmọ̀ dání, àwọn olórí àlùfáà, àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbààgbà ló rán wọn wá.+ 44 Ẹni tó fẹ́ dà á ti fún wọn ní àmì kan tó jọ yé wọn, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fẹnu kò lẹ́nu, òun ni ẹni náà; kí ẹ mú un, kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ bí ẹ ṣe ń mú un lọ.” 45 Ó wá tààràtà, ó sì sún mọ́ ọn, ó sọ pé: “Rábì!” ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 46 Torí náà, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un sọ́dọ̀.

  • Jòhánù 18:2, 3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Júdásì, ẹni tó dà á náà mọ ibẹ̀, torí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sábà máa ń pàdé níbẹ̀. 3 Torí náà, Júdásì kó àwùjọ àwọn ọmọ ogun àti àwọn òṣìṣẹ́ ti àwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí, wọ́n sì wá síbẹ̀, tàwọn ti ògùṣọ̀, fìtílà àti ohun ìjà.+

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́