24 Jésù sọ pé: “Ẹ kúrò níbẹ̀, torí ọmọdébìnrin náà ò kú, ó ń sùn ni.”+ Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń fi ṣẹlẹ́yà. 25 Gbàrà tí wọ́n ní kí àwọn èrò náà bọ́ síta, ó wọlé, ó di ọwọ́ ọmọdébìnrin náà mú,+ ọmọ náà sì dìde.+
14 Ló bá sún mọ́ wọn, ó fọwọ́ kan àga ìgbókùú* náà, àwọn tó gbé e sì dúró. Ó wá sọ pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo sọ fún ọ, dìde!”+15 Ọkùnrin tó ti kú náà wá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, Jésù sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.+
43 Nígbà tó sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbóhùn sókè, ó sọ pé: “Lásárù, jáde wá!”+44 Ọkùnrin tó ti kú náà jáde wá, tòun ti aṣọ tí wọ́n fi dì í tọwọ́tẹsẹ̀ àti aṣọ tí wọ́n fi di ojú rẹ̀. Jésù sì sọ fún wọn pé: “Ẹ tú u, kí ẹ jẹ́ kó máa lọ.”