52 Àmọ́ gbogbo èèyàn ń sunkún, wọ́n sì ń lu ara wọn bí wọ́n ṣe ń dárò torí ọmọ náà. Torí náà, ó sọ pé: “Ẹ má sunkún mọ́,+ torí kò kú, ó ń sùn ni.”+ 53 Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń fi ṣẹlẹ́yà, torí wọ́n mọ̀ pé ọmọ náà ti kú. 54 Àmọ́ ó dì í lọ́wọ́ mú, ó sì pè é, ó ní: “Ọmọ, dìde!”+