-
Mátíù 20:20-23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ìyá àwọn ọmọ Sébédè+ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ wá bá a, obìnrin náà tẹrí ba* fún un, ó sì béèrè ohun kan lọ́wọ́ rẹ̀.+ 21 Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Kí lo fẹ́?” Ó fèsì pé: “Pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ mi méjèèjì yìí jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú Ìjọba rẹ.”+ 22 Jésù dáhùn pé: “Ẹ ò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè. Ṣé ẹ lè mu ife tí mo máa tó mu?”+ Wọ́n sọ fún un pé: “A lè mu ún.” 23 Ó sọ fún wọn pé: “Ó dájú pé ẹ máa mu ife mi,+ àmọ́ èmi kọ́ ló máa sọ ẹni tó máa jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi àti sí òsì mi, ṣùgbọ́n ó máa wà fún àwọn tí Baba mi ti ṣètò rẹ̀ fún.”+
-
-
Lúùkù 11:49Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
49 Ìdí nìyẹn tí ọgbọ́n Ọlọ́run náà fi sọ pé: ‘Màá rán àwọn wòlíì àti àwọn àpọ́sítélì sí wọn, wọ́n máa pa àwọn kan, wọ́n sì máa ṣe inúnibíni sí àwọn kan lára wọn,
-