-
1 Tímótì 1:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Bí mo ṣe gbà ọ́ níyànjú nígbà tí mo fẹ́ lọ sí Makedóníà pé kí o dúró ní Éfésù, bẹ́ẹ̀ náà ni mò ń ṣe báyìí, kí o lè pàṣẹ fún àwọn kan pé kí wọ́n má ṣe fi ẹ̀kọ́ tó yàtọ̀ kọ́ni, 4 kí wọ́n má sì tẹ́tí sí àwọn ìtàn èké+ àti àwọn ìtàn ìdílé. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kò wúlò rárá,+ ṣe ló ń mú káwọn èèyàn máa méfò dípò kó máa fúnni ní ohunkóhun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́.
-
-
1 Tímótì 6:3-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Tí ẹnikẹ́ni bá fi ẹ̀kọ́ míì kọ́ni, tí kò sì fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní,*+ tó wá látọ̀dọ̀ Olúwa wa Jésù Kristi àti ẹ̀kọ́ tó bá ìfọkànsin Ọlọ́run mu,+ 4 ó ń gbéra ga, kò sì lóye ohunkóhun.+ Ìjiyàn àti fífa ọ̀rọ̀ ló gbà á lọ́kàn.*+ Àwọn nǹkan yìí máa ń fa owú, wàhálà, bíbanijẹ́,* ìfura burúkú, 5 ṣíṣe awuyewuye lemọ́lemọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan láàárín àwọn èèyàn tí ìrònú wọn ti dìbàjẹ́,+ tí wọn ò mọ òtítọ́, tí wọ́n sì ń ronú pé èrè ni ìfọkànsin Ọlọ́run wà fún.+
-