23 Ó lọ káàkiri gbogbo Gálílì,+ ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn,+ ó sì ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ó ń wo onírúurú àìsàn àti onírúurú àìlera sàn láàárín àwọn èèyàn.+
7 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ atótónu,* Pétérù dìde, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ mọ̀ dáadáa pé tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti yàn mí láàárín yín pé kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere látẹnu mi, kí wọ́n sì gbà gbọ́.+
23 kìkì pé kí ẹ dúró nínú ìgbàgbọ́,+ kí ẹ fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà,+ kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin,+ kí ẹ má yà kúrò nínú ìrètí ìhìn rere tí ẹ gbọ́, tí a sì ti wàásù láàárín gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.+ Torí ìhìn rere yìí la ṣe yan èmi Pọ́ọ̀lù láti di òjíṣẹ́.+