3 Ẹ bá mi kí Pírísíkà àti Ákúílà,+ àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ Kristi Jésù, 4 àwọn tí wọ́n fi ẹ̀mí* ara wọn wewu nítorí mi,*+ kì í ṣe èmi nìkan ló ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè pátá náà ń dúpẹ́.
8 Torí náà, bí a ṣe ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí yín, a ti pinnu* pé kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan la máa fún yín, a tún máa fún yín ní ara* wa,+ torí ẹ ti di ẹni ọ̀wọ́n sí wa.+